Full width home advertisement

Travel the world

Climb the mountains

Post Page Advertisement [Top]

Akori Adura: ITUSILE KURO LOWO IGBEKUN EBUN OKUNKUN
Ese Bibeli: Efesu 6:10-12
Ojo oni je ojo pataki ninu iran eniyan kakiri agbaye ti nse afihan fifi ebun fun enikeji wa, sugbon opolopo eniyan loti padanu ise, Ogo, Ola, ayo, it ati bebelo nipase ebun buburu ti won gba ni ayajo ojo oni. Fifi ebun fun enikeji wa gegebi asa ati ise ojo oni je ohun pataki tio si dara pupo lati mase kise ni ojo oni Numan, sugbon nigbagbogbo gegebi Bibeli se so fun wa lati mase. Sugbon o se ni lanu pe idi rere nipa fifi ebun fun enikeji wa ni awon ota ti yi pada si ohun miran lati ma fi se ijamba ati idamu fun awon eniyan ti won fi ebun bee fun.
Ebun je ohun ti o ma nfo eniyan loju, ti opolopo eniyan si wa ninu idamu ati aini aseyori nipa gbigba ebun buburu ni ayajo ojo oni.
"Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀. Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi." Ezekiel 22:11-12
Opo Ogo loti sonu, ti opolopo ayanmo si wa ninu Igbekun ota nitori ebun ojo kan. Opo omobirin ati omokunrin ni won tita ogo ati ojo ola won nipase ebun buburu ti won gba lowo ore. Ogun ifaseyin ati ailakojo ti o nba elomiran jagun loduro lori ipile ebun buburu ti won gba laimo. Iku aitojo ati aisan mo da ohunrere se je baraku fun opolopo nitori ebun okunkun ti won gba layajo ojo oni lowo awon ota asekupani.
Arakunrin ati arabinrin, nikorita yi mo fe ki o ye ara re wo daradara nitoripe osese ki o ti gba awon ebun buburu ti o fi o sinu idekun ati Igbekun todojuko o. Asise nla ni ki o gba ebun nitoripe okunrin fe ba o dapo.
Asise nla ki o se ibalopo pelu enikeni ti ki se oko tabi aya re, sugbon opolopo gba laaye lati ba o lajosepo nitori o fun tabi gba ebun lowo re. Ebun owo, phone, iPad, aso, bata, gele, ati ohun meremere miran ti o gba tabi ti opinu lati gba lowolowo le je idekun okunkun to le dena aseyori ati ojo ola mo o, kiyesara gidigidi.
Opo igbeyawo loti daru nipa ebun buburu ti oko tabi aya ti gba laimo.
Opo ise ati okowo ni oti daru ti igbe aye eniti o ni okowo ati ise ti di eti yeye lawajo. Sugbon loni, opin de ba ogun lona loni loruko Jesu. Gbiyanju lati gba adura toni yi pelu igbagbo ati otito ninu agbara Olorun oga Ogo.
ADURA ARA:
1. Oluwa mo dupe fun ore-ofe ti mori gba lowo Re lati gbo eko ti oni.
2. Gbogbo majemu ati agbara ebun buburu ti o nyo mi lenu e ma jona loruko Jesu
3. Irugbin ebun okunkun ninu aye mi, e ma fatu loruko Jesu
4. Gbogbo iserere ati ogo ti mo ti sonu nipa ebun buburu ti mo gba, mo gba won pada loruko Jesu
5. Gbogbo ebun buburu to so aye mi kodo, e doku loruko Jesu
6. Mo ko lati wa lati wa labe ide ebun buburu loruko Jesu
7. Lati oni lo mo di ominira kuro lowo ide ebun okunkun loruko Jesu
8. Oluwa fi opin si iwalaye agbara ebun okunkun ninu aye mi loruko Jesu
9. Alagbara okunkun to pinu lati fi ebun buburu fun mi lojo oni, gba idalebi loruko Jesu
10. Mo ko ebunkebun ti yo se iku pami loruko Jesu.

No comments:

Post a Comment

Bottom Ad [Post Page]