Full width home advertisement

Travel the world

Climb the mountains

Post Page Advertisement [Top]


Akori: IYANU WAKATI IKEHIN

Bibeli Kika 2 Awon Oba 2:1-15, Luku 23:39-43

Ope ni fun Olorun to da emi wasi titidi oni. Laise awawi odun 2018 nlo sopin laipe. Opo iyanu ti ko ni afiwe wa ninu ojo melo toku ninu odun yi. O sese ki o ti lepa awon iyanu kan sugbon ti owo re koti te, modajupe wakati toku ninu odun yi isere naa yoo te o lowo.

Ni wakati ikehin ti Woli Elijah yoo pari ise iranse re, Elisha to je Omo eyin re ridajupe oun gba iyanu wakati ikehin lowo Olorun ki oga oun to lo. Bakanna ni odaran to wa lori igi pelu Jesu ridajupe oun gba iyanu ikehin lowo Jesu ki Jesu to lo tan. 2 Awon Oba 2:9-10, Luku 23:42-43.

Iyanu ikehin je iyanu ailegbe ati ailafiwe ti enikeni le gba lowo Olorun niwon igbati o ba ti se tan, ti o si gbe igbese akoni bi ti Elisha ati odaran ti a ka nipa won ninu Bibeli. 

Awon Ohun Patalki ti O gbudo Se Ki O Le gba iyanu ikehin:

1. Pinu lati ri iyanu ikehin gba lowo Olorun 

2. Di Jesu Kristi mu girigiri laisare ati laisimi.

3. Beere iyanu ikehin ti iwo nfe lowo Olorun 

4. Pa awon ota re lenu mo. Mase gba oro odi ti ota nso gbo. Mase gba idiwo laaye rara. 

5. Mase so ireti nu titi too fi gba iyanu ikehin lowo Olorun. 

ADURA ARA:

1. Baba mi ati Olorun mi, modupe fun isiniye nipa oro Re. 

2. Emi akin ti ma fi gba iyanu ikehin wonu mi lo loruko Jesu 

3. Gbogbo ijoba oludena loju ona iyanu ikehin mi, ina ati ara pin yin niya loruko Jesu 

4. Iyanu ikehin mo gba loruko Jesu 

5. Ogo ikehin fun odun 2018 mogba pada loni loruko Jesu 

6. Aseyori ikehin fun odun 2018, mogba loni loruko Jesu 

7. Ibukun ikehin fun odun yi mo gba loruko Jesu 

8. Iranlowo ikehin fun idalola alailegbe fun odun 2018 mo gba loruko Jesu 

9. Ise iyanu ikehin fun odun 2018, mogba pada loruko Jesu 

10. Isele iyanu ayo ti yoo pa awon ota mi lekun, loruko Jesu yoo sele simi ki odun 2018 yi to pari 

11. Igbega ikehin ninu ohun rere fun odun 2018 yoo je titemi loruko Jesu 

12. Mo gba Leta ayo fun Iranlowo ti ko legbe fun wakati ikehin ninu odun 2018 ni oruko Jesu 

13. Gbogbo agbara okunkun to pinu lati de mi lona iyanu ikehin fun odun yi, ina ati ara tu won ka loruko Jesu

No comments:

Post a Comment

Bottom Ad [Post Page]