Full width home advertisement

Travel the world

Climb the mountains

Post Page Advertisement [Top]

ARA ADURA FUN OJO ONI (24/12/2018)

AKORI ADURA: BIBO LOWO OGUN AYE ILERI

ESE BIBELI KIKA: JOHANU 7:1

John 7:1 "LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a."

Ni akoko ti Jesu nwasu ihinrere Re,  awon kan nwa ona lati pa ki akoko iku Re fun igbala awa eniyan to ko. Awon asekupani yi fe ye ileri ati akosile Olorun fun Jesu Kristi. Sugbon Jesu Kristi funrare mo wipe awon ota wonyi fe ye ileri Olorun ninu aye oun, O si gbe igbese ti imo won kofinise. 

Arakunrin ati arabinrin, Opo ileri Olorun ni o wa pelu wa ni ibere odun yi,  sugbon fun idi kan ati omiran, ileri yi koti wa si imuse. Mo fe ki olukuluku ronu ki o si ye ara re wo, nje ileri Olorun fun o ninu odun 2018 to npari lo ti se ninu aye re tabi lori ise re, tabi lori eto isuna re, tabi lori igbeyawo ati idile re,  tabi lori eko ati ile-iwe re, tabi lori ise iranse re, etc. 

Modaju wipe, ti o ba le gba adura ti oni yi pelu igbagbo, awon ileri bee yo se ninu aye re ki odun yi to pari. Sugbon o gbodu mo eniti Jesu nse gegebi olugbala re, ati enikan soso to mu ki ileri se ninu aye re. 

Ese ati iwa aigboran je awon idena fun ileri Olorun ninu aye re. Awon ota alatako ohun rere je oludena fun imuse ileri Olorun. Kiko Egbe buburu tun je Idena miran ti ileri Olorun kofi se ninu aye opolopo eniyan loni. 

Arakunrin ati arabinrin, iru egbe wo lowa? Awon wo lonbarin? Iru iwa wo nwu?  Mo bee o,  ye ara re wo daradara ki o si ronupiwada ki o to gbadura wonyi. 2Kronika 7:14.

Awon ADURA ARA:

1. Gbogbo ijoba ati agbara okunkun to nye ileri Olorun ninu aye MI, ina ati ara Olorun ko tu yi ka ni oruko Jesu. 

2. Gbogbo majemu aye ileri ohun rere ninu aye MI, mo pa yin re pelu eje Jesu Kristi. 

3. Gbogbo ago aye ileri ohun rere ti ota gbe wo mi, mo fa ya pelu ina ni oruko Jesu 

4. Baba mi ati Olorun mi, jamigba lowo ogun aye ileri to nyo mi lenu ni oruko Jesu 

5. Gbogbo iserere gbogbo ti Olorun ko mo mi ninu odun 2018, ninu oruko Jesu mo gba won pada. 

6. Bata aye ileri ti afiwomi ninu okunkun,  mo bo danu ni oruko Jesu 

7. Gbogbo irugbin ayeleri ninu aye MI e ma fa tu loruko Jesu 

8. Sekeseke aye ileri ninu aye MI, e ma ja danu pelu ina ati ara ni oruko Jesu. 

9. Gbogbo ona iserere ti ogun ayeleri ti di mo mi,  loruko Jesu e ma sii. 

10. Lati oni lo,  modi ominira kuro lowo ogun ayeleri ni oruko Jesu Kristi.

No comments:

Post a Comment

Bottom Ad [Post Page]