Full width home advertisement

Travel the world

Climb the mountains

Post Page Advertisement [Top]

Akori Adura: IRAWO MI YOO TAN KARI AYE
Ese Bibeli: Mattiu 2:1-10
Ni akoko ti won bi Jesu Kristi, ohun akoko to se afihan Re ni irawo Re. Awon amoye ri irawo Jesu ni ona jinjinrere, won si to wa. Irawo je ohun to se afihan eniyan. Eniyan kokan loni irawo to nse afihan re kari aye.
Irawo eniyan je ohun ti awon ota ma nwo ti won si ma nlepa lati pa ati latiparun. Awon amoye wa irawo Jesu Kristi ri lati bu ola, ati ola fun un. Sugbon oba Herodu ati awon igbimo re nwa irawo Jesu lati pa ati lati parun. sugbon nitoripe Jesu Kristi je Omo Olorun oga Ogo, ati wipe O wa fun idi pataki lati sise igbala fun gbogbo eniyan nipa iku ati ajinde Re. Johanu 3:16-18
Gegebi Jesu Kristi se wa si aye fun ise igbala gbogbo eniyan, beni iwo pelu se wa si aye yi fun ise pataki. Bi oba Herodu ati awon igbimo re se wa ona lati pa Jesu Kristi bee gege ni awon ota nwa ona lati pa irawo ati eniti oni irawo.
Opo irawo awon eniyan ni won ti pa, ti opo irawo awon eniyan si wa ninu Igbekun awon ota ati ijoba okunkun. Opo irawo awon eniyan ni ko tan mo nitoripe agbara okunkun ti fi pamo. Opolopo lowa ninu ide afi irawo pamo, ti opolopo eniyan si wa ninu idamu ati aini aseyori.
Ti irawo eniyan ko bati tan moo, Ogo eniyan be ko le tan. Ti irawo eniyan bawa ninu ahamo awon ota, Kosi aniani pe igbe aye eni bee yoo wa ninu Igbekun bi amubo ohun rere, ikuna ni ikorita aseyori, ijakule, aisan ati bebelo.
Arakunrin ati arabinrin, bi ase nse ajoyo ojo ibi Jesu Kristi loni, mofe ki o mo pe awon ota bi Herodu wa layika re to nwa ona lati pa irawo ati Okiki Ogo re. Aimoye awon Herodu nile baba ati Iya re to nwa ona lati pa o ati lati pa ogo re pelu irawo re. Sugbon mo gba Olorun gbo pe bi Olorun ti so imo Herodu ati awon igbimo re di asan lori Jesu Kristi beni yoo so imo won di asan lori re loni.
Sugbon ridajupe o gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala re tokantokan. Yago fun itanje satani ati awon igbimo re. Je olugboran gegebi awon amoye. Ridajupe o nsin Jesu ninu ewa iwa Mimo. Ki o si gba awon adura ara yi daradara.

AWON ADURA ARA:
1. Irawo mi gbo oro Oluwa, jade Kuro ninu Igbekun awon ota ni oruko Jesu
2. Agbara okunkun to gbe irawo mi hanu, iro lopa, po irawo mi sile loruko Jesu.
3. Gbogbo agbara okunkun to nyo irawo mi lenu e ma jona loruko Jesu.
4. Ogun aparawo, iro lepa, e ma doku loruko Jesu
5. Gbogbo egbe aje to nyo irawo mi lenu, e ma do ku loruko Jesu
6. Baba mi ooooo, e fi owo agbara nla yin fa Ogo MI jade kuro ninu Igbekun awon ota loruko Jesu
7. Gbogbo egbe eleye lori irawo MI, ara ati ina Olorun tu yin ka loruko Jesu
8. Pelu agbara eje Jesu, irawo mo palase bere sini tan kari aye loruko Jesu
9. Ogo irawo mi, e wo lo nse lawajo gbese, jade loruko Jesu.

No comments:

Post a Comment

Bottom Ad [Post Page]